ÌTÀN YÍ ṢẸLẸ̀ LÓÒÓTỌ́
Láti ẹnu –Olùṣọ́ àgùntàn E. A. Adeboye
"Nígbà tí mo wà ní màjèṣín, ẹ̀gbọ́n mi àgbà (tí a kìí ṣe ọmọ ìyá kan náà) rin ìrìn àjò lọ sí ìletò tó súnmọ́ wa, nígbàtí ó sì ń darí bọ̀, ó mú fìlà kan bọ̀. Fìlà náà rẹwà púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, kódà ẹwà rẹ̀ kò láfiwe pàápàá sí àwa ọmọdé náà nítorí ọmọ ò rírú ẹ rí ni wa. Látàrí èyí, gbogbo wa yí i ká, a sì ń gbé Fìlà náà yẹ̀wò.
Ó wá ṣe ohun kàn tó jọ mí lójú púpọ̀. Ó bọ́ fìlà náà lórí, ó sì de lé mi lórí. 'Hà! ẹ gbàmí láàyè láti dé ohun tó rẹwà yìí?' Gbogbo àwọn ọmọdé tí a jọ wà níbẹ̀ ni ẹnu yà, tí wọ́n sì ń dunnú fún mi.
Lẹ́yìn èyí, ó sọ ohun kan tí n kò gbàgbọ́. Ó wí fún mi pé 'mo rà á fún ọ'. Mo férẹ̀ le dákú látàrí bí inú mi ti dùn tó. Ìṣẹ̀lẹ̀ yí ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1950. Ọdún gorí ọdún, nígbà tó sì di lẹ́yìn bí ọdún méjìlélógún, mo sùn lálẹ́, ṣùgbọ́n n kò rí oorun sùn, fún ìdí kan tàbí òmíràn, ọkàn mi rántí ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ kìíní àná, nítorípé mò ń ṣàṣàrò lórí ìgbé ayé mi, mò ń ronú àwọn ọjọ́ dáradára, ọkàn mi sì rántí ọjọ́ náà.
Ìbéèrè kan wá sí mi lọ́kàn. ‘kí ni o ti ṣe fún arákùnrin yìí?’. Fún ìdí èyí, mo pinnu lọ́kàn mi nípa ohun tí n ó ṣe. Lọ́jọ́ kan, ẹ̀gbọ́n mi jókòó níwájú ìta lábúlé wa. Akúṣẹ̀ẹ́ àgbẹ̀ lásán ni tí kò tilẹ̀ rí owó ra kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́mu lásán. Dẹ́rẹ́bà mi àti ẹlòmíràn wa ọkọ̀ lọ sí ilé wa lábúlé. Ṣáájú àkókò yí, bí wọ́n báti gbóhùn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ níwájú ilé wa, wọn á ti mọ̀ wípé mo ti wọ̀lú. Ó bọ́ sóde pẹ̀lú àwọn tó wà nínú ilé nígbà náà, ó sì béèrè pẹ̀lú ìyàlẹ́nu wípé ‘èétirí! Ibo ni Bàbá Alákòóso wà?’
Dẹ́rẹ́bà fèsì wípé ‘hà! wọn kò tẹ̀lé wa wá o’
Ẹ̀gbọ́n mi bá dáhùn wípé ‘kò burú. Kí wá lẹ wá ṣe?’
‘Bàbá Alákòóso ní ká wí fún un yín wípé, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ yìí ti di tiyín, ọ̀gbẹ́ni ẹ̀gbẹ́ mi yìí ni yóò sì jẹ́ dẹ́rẹ́bà yín. Wọ́n ní àwọn yóò máa 'san owó oṣù dẹ́rẹ́bà, wọn yóò máa bá a yín ra epo sọ́kọ̀, àwọn yóò sì máa bá a yín ṣe àwọn àtúnṣe tó bá pè fún lára ọkọ̀ náà.’
Ẹ̀gbọ́n mi fèsì wípé, ‘kí ni ohun tí ẹ̀ ń wí?’
Dẹ́rẹ́bà mi bá fèsì padà wípé, ‘iṣẹ́ tí wọ́n ní a jẹ́ fún un yín nìyẹn’.
Wọ́n padà jábọ̀ fún mi wípé, nígbà tí àwọn jẹ́ iṣẹ́ náà tán, òòyì ojú kọ́ ẹ̀gbọ́n mi tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọ́n gbé àga fún wọn láti jókòó.
"BÁYÌÍ GẸ́LẸ́ NI Ó ṢE ṢE MI NÍ ỌDÚN 1950."
......................................
Ní àkókò tí a wà yí, àwọn tí ọ̀run ti yàn láti ran àyànmọ́ rẹ lọ́wọ́ kò níí ní ìsinmi títí wọn yóò fi bùkún fún ọ ní orúkọ ńlá ti Jésù!
Comments
Post a Comment